a (Gk): Hb 12.13.

Proverbs 4

Ọgbọ́n ni o ga jùlọ

1Tẹ́tí, Ẹ̀yin ọmọ mi, sí ẹ̀kọ́ baba; fetísílẹ̀ kí o sì ní òye sí i
2Mo fún ọ ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro
Nítorí náà má ṣe kọ ẹ̀kọ́ mi sílẹ̀
3Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ní ilé baba à mí,
mo jẹ́ èwe, tí mo sì jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi
4Ó kọ́ mi ó sì wí pé
“Jẹ́ kí àyà rẹ kí ó gba ọ̀rọ̀ mi dúró,
pa òfin mi mọ́, kí ìwọ kí ó sì yè.
5Gba ọgbọ́n, gba òye,
Má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹsẹ̀ kúrò nínú rẹ̀
6Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́,
fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojútó ọ.
7Ọgbọ́n ni ó ga jù; nítorí náà gba ọgbọ́n.
Bí ó tilẹ̀ ná gbogbo ohun tí o ní, gba òye
8Gbé e ga, yóò sì gbé ọ ga
dìrọ̀ mọ́ ọn, yóò sì bu iyì fún ọ.
9Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹ
yóò sì fi adé ẹlẹ́wà fún ọ.”

10Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ,
Ọjọ́ ayé è rẹ yóò sì gùn.
11Mo tọ́ ọ ṣọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́n
mo sì mú ọ lọ ní ọ̀nà ti tààrà.
12Nígbà tí o rìn, ìgbésẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́
nígbà tí o bá sáré, ìwọ kì yóò kọsẹ̀.
13Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ;
tọ́jú u rẹ̀ dáradára nítorí òun ni ìyè rẹ.
14Má ṣe gbé ẹsẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú
tàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.
15Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀;
yàgò fún un kí o sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ
16Nítorí wọn kò le sùn àyàfi tí wọ́n bá ṣe ibi,
wọn kò ní tòògbé àyàfi tí wọ́n bá gbé ẹlòmíràn ṣubú
17Wọ́n ń jẹ oúnjẹ ìwà búburú
wọ́n sì ń mu wáìnì ìwà ìkà.

18Ipa ọ̀nà olódodo dàbí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn
tí ń tànmọ́lẹ̀ sí i títí ọjọ́ fi kanrí
19ṣùgbọ́n ọ̀nà ènìyàn búburú dàbí òkùnkùn biribiri;
wọn kò mọ ohun tí ó ń mú wọn kọsẹ̀.

20Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ;
fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi
21Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójú
pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ;
22Nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó rí wọn
àti ìlera fún gbogbo ara ènìyàn
23Ju gbogbo nǹkan tókù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́
Nítorí òun ni orísun ìyè,
24Mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ;
sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ.
25Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo iwájú,
jẹ́ kí ìwo ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sá á.
26 aKíyèsi ìrìn ẹsẹ̀ rẹ
sì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan
27Má ṣe yà sọ́tùn ún tàbí sósì;
pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú ibi.
Copyright information for YorBMYO